Ìṣe Àwọn Aposteli 12:21-25 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Nígbà tí ó di ọjọ́ tí ọba dá fún wọn, Hẹrọdu yọ dé pẹlu aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó wá bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀.

22. Ni àwọn eniyan náà bá ń kígbe pé, “Ohùn Ọlọrun nìyí, kì í ṣe ti eniyan!”

23. Lẹsẹkẹsẹ angẹli Oluwa bá lù ú pa, nítorí kò fi ògo fún Ọlọrun. Ni ìdin bá jẹ ẹ́ pa.

24. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń tàn káàkiri.

25. Nígbà tí Banaba ati Saulu parí iṣẹ́ tí a rán wọn, wọ́n pada láti Jerusalẹmu, wọ́n mú Johanu tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Maku lọ́wọ́.

Ìṣe Àwọn Aposteli 12