4. Ó ní ipò tí ó ga ju ti àwọn angẹli lọ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ní orúkọ tí ó ju tiwọn lọ.
5. Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé,“Ìwọ ni ọmọ mi,lónìí ni mo bí ọ?”Tabi tí ó sọ fún pé,“Èmi yóo jẹ́ baba fún un,òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?”
6. Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé,“Kí gbogbo àwọn angẹliỌlọrun foríbalẹ̀ fún un.”
7. Ohun tí ó sọ nípa àwọn angẹli ni pé,“Ẹni tí ó ṣe àwọn angẹli rẹ̀ ní ẹ̀fúùfù,tí ó ṣe àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ ní ọwọ́ iná.”
8. Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé,“Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun,ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ.