Ẹsita 4:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Modekai gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Ó fi àkísà ati eérú bo ara rẹ̀. Ó kígbe lọ sí ààrin ìlú, ó ń pohùnréré ẹkún.

2. Ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn kò wọlé nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wọ àkísà wọ inú ààfin.

Ẹsita 4