Ẹsira 4:18-21 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Wọ́n ka ìwé tí ẹ kọ sí wa, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ níwájú mi.

19. Mo pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìwádìí, a sì rí i pé láti ayébáyé ni ìlú yìí tí ń ṣọ̀tẹ̀ sí àwọn ọba wọn.

20. Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerusalẹmu, wọ́n ti jọba lórí gbogbo agbègbè òdìkejì odò, wọ́n sì gba owó ìṣákọ́lẹ̀, owó bodè lọ́wọ́ àwọn eniyan.

21. Nítorí náà, ẹ pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró títí wọn yóo fi gbọ́ àṣẹ mìíràn láti ọ̀dọ̀ mi.

Ẹsira 4