7. OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́,ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́;wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWAgẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀.
8. OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀.Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n,kò sì rowọ́ láti parun.Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́,wọ́n sì di àlàpà papọ̀.
9. Àwọn ẹnubodè rẹ̀ ti rì, wọ́n ti wọlẹ̀;ó ti ṣẹ́ àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè;ọba rẹ̀ ati àwọn olórí rẹ̀ wà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn;òfin kò sí mọ́, àwọn wolii rẹ̀ kò sì ríran láti ọ̀dọ̀ OLUWA mọ́.