20. “Bojúwò mí, OLUWA,nítorí mo wà ninu ìpọ́njú,ọkàn mi ti dàrú, inú mi bàjẹ́,nítorí pé mo ti hùwà ọ̀tẹ̀ lọpọlọpọ.Níta gbangba, ogun ń pa mí lọ́mọ;bákan náà ni ikú ń bẹ ninu ilé.
21. “Gbọ́ bí mo ti ń kérora,kò sí ẹnìkan tí yóo tù mí ninu.Gbogbo àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ nípa ìyọnu mi;inú wọn sì dùn,pé ìwọ ni o kó ìyọnu bá mi.Jẹ́ kí ọjọ́ tí o dá tètè pé,kí àwọn náà lè dàbí mo ti dà.
22. “Ranti gbogbo ìwà ibi wọn,kí o sì jẹ wọ́n níyà;bí o ti jẹ mí níyà,nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”