Diutaronomi 5:8-13 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “ ‘O kò gbọdọ̀ yá èrekére kankan fún ara rẹ, kì báà jẹ́ ní àwòrán ohunkohun tí ó wà ní ojú ọ̀run tabi ti ohun tí ó wà lórí ilẹ̀, tabi èyí tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀.

9. O kò gbọdọ̀ tẹríba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ sìn wọ́n, nítorí pé Ọlọrun tíí máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ ati ọmọ ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ìran kẹrin ninu àwọn tí wọ́n kórìíra mi.

10. Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi, tí kì í yẹ̀, hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi, tí wọ́n sì ń tẹ̀lé òfin mi.

11. “ ‘O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán; nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi.

12. “ ‘Ya ọjọ́ ìsinmi sọ́tọ̀, kí o sì ṣe é ní ọjọ́ mímọ́, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun rẹ ti pàṣẹ fún ọ.

13. Ọjọ́ mẹfa ni kí o fi ṣe gbogbo làálàá ati iṣẹ́ rẹ;

Diutaronomi 5