5. “Obinrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti ọkunrin, bẹ́ẹ̀ sì ni ọkunrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọkáṣọ tí ó bá jẹ́ ti obinrin nítorí pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìríra ni ó jẹ́ lójú OLUWA Ọlọrun yín.
6. “Bí ẹ bá rí ìtẹ́ ẹyẹ lórí igi tabi ní ilẹ̀, tí ẹyin tabi ọmọ bá wà ninu rẹ̀, tí ìyá ẹyẹ yìí bá ràdọ̀ bò wọ́n, tabi tí ó bá sàba lé ẹyin rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ ẹyẹ náà pẹlu ìyá wọn.
7. Ẹ níláti fi ìyá wọn sílẹ̀ kí ó máa lọ ṣugbọn ẹ lè kó àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè dára fun yín, kí ẹ sì lè pẹ́ láyé.
8. “Tí ẹ bá kọ́ ilé titun, ẹ níláti ṣe ìgbátí sí òrùlé rẹ̀ yípo, kí ẹ má baà wá di ẹlẹ́bi bí ẹnikẹ́ni bá jábọ́ láti orí òrùlé yín, tí ó sì kú.
9. “Ẹ kò gbọdọ̀ gbin ohunkohun sáàrin àwọn àjàrà tí ẹ bá gbìn sinu ọgbà àjàrà yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àjàrà náà, ati ohun tí ẹ gbìn sáàrin rẹ̀ yóo di ti ibi mímọ́.
10. “Ẹ kò gbọdọ̀ so àjàgà kan náà mọ́ akọ mààlúù ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ́rùn, láti fi wọ́n ṣiṣẹ́ ninu oko.