9. Lára ọ̀kan ninu àwọn ìwo mẹrin ọ̀hún ni ìwo kékeré kan ti yọ jáde, ó gbilẹ̀ lọ sí ìhà gúsù, sí ìhà ìlà oòrùn ati sí Ilẹ̀ Ìlérí náà.
10. Ó tóbi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ń bá àwọn ogun ọ̀run jà, ó já àwọn kan ninu àwọn ìràwọ̀ lulẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.
11. Ó gbé ara rẹ̀ ga, títí dé ọ̀dọ̀ olórí àwọn ogun ọ̀run. Ó gbé ẹbọ sísun ojoojumọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ibi mímọ́ rẹ̀.
12. A fi ogun náà ati ẹbọ sísun ojoojumọ lé e lọ́wọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, a sì já òtítọ́ lulẹ̀. Gbogbo ohun tí ìwo náà ń ṣe, ni ó ṣe ní àṣeyọrí.