Àwọn Ọba Kinni 6:28-34 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Wúrà ni wọ́n yọ́ bo àwọn Kerubu náà.

29. Wọ́n gbẹ́ àwòrán igi ọ̀pẹ, ati ti òdòdó, ati ti Kerubu yípo ara ògiri yàrá tí ó wà ninu ati èyí tí ó wà lóde;

30. wọ́n sì yọ́ wúrà bo ilẹ̀ àwọn yàrá náà.

31. Wọ́n ri ìlẹ̀kùn meji, alápapọ̀, tí wọ́n fi igi olifi ṣe, mọ́ ẹnu ọ̀nà Ibi-Mímọ́-Jùlọ. Àtẹ́rígbà ìlẹ̀kùn náà rí ṣóńṣó ní ààrin,

32. wọ́n gbẹ́ igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati kerubu sí ara àwọn ìlẹ̀kùn náà; wọ́n sì yọ́ wúrà bò wọ́n patapata: ati igi ọ̀pẹ, ati òdòdó, ati àwọn Kerubu náà.

33. Wọ́n fi igi olifi ṣe férémù ìlẹ̀kùn onígun mẹrin, wọ́n rì í mọ́ ẹnu ọ̀nà àbáwọ gbọ̀ngàn ńlá.

34. Wọn fi igi sipirẹsi ṣe ìlẹ̀kùn meji, ekinni keji ní awẹ́ meji, awẹ́ ekinni keji sì ṣe é pàdé mọ́ ara wọn.

Àwọn Ọba Kinni 6