1. Nígbà tí Hiramu, ọba Tire, gbọ́ pé Solomoni ni ó gun orí oyè lẹ́yìn baba rẹ̀, ó rán oníṣẹ́ sí i; nítorí ọ̀rẹ́ ni òun ati Dafidi, wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn.
2. Solomoni náà ranṣẹ pada sí Hiramu,
3. ó ní, “Ìwọ náà mọ̀ pé Dafidi, baba mi, kò lè kọ́ ilé ìsìn fún OLUWA Ọlọrun rẹ̀ nítorí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni ó fi bá àwọn ọ̀tá rẹ̀ tí wọ́n yí i ká jagun, títí tí OLUWA fi fún un ní ìṣẹ́gun lórí wọn.