10. Inú OLUWA dùn fún ohun tí Solomoni bèèrè.
11. Ọlọrun sì dá a lóhùn, ó ní, “Nítorí pé ọgbọ́n láti mọ ohun tí ó dára ni o bèèrè, tí o kò bèèrè ẹ̀mí gígùn, tabi ọpọlọpọ ọrọ̀ fún ara rẹ, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ,
12. wò ó! N óo fún ọ ní ohun tí o bèèrè. Ọgbọ́n ati òye tí n óo fún ọ yóo tayọ ti gbogbo àwọn aṣiwaju rẹ, ati ti àwọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ.
13. N óo fún ọ ní ohun tí o kò tilẹ̀ bèèrè. O óo ní ọrọ̀ ati ọlá tóbẹ́ẹ̀ tí kò ní sí ọba kan tí yóo dàbí rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
14. Bí o bá ń gbọ́ tèmi, tí o sì ń pa gbogbo àwọn òfin, ati àwọn ìlànà mi mọ́, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ ti ṣe, n óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùn pẹlu.”
15. Nígbà tí Solomoni tají, ó rí i pé àlá ni òun ń lá, ó bá lọ sí Jerusalẹmu, ó lọ siwaju Àpótí Ẹ̀rí OLUWA, ó sì rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó se àsè ńlá fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀.
16. Ní ọjọ́ kan, àwọn aṣẹ́wó meji kan kó ara wọn wá siwaju Solomoni ọba.