8. Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.”Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”
9. Ahabu bá pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ ní ààfin pé kí ó lọ pe Mikaaya, ọmọ Imila, wá kíákíá.
10. Ọba Israẹli ati Jehoṣafati ọba Juda wọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì jókòó lórí ìtẹ́ wọn, ní ibi ìpakà tí ó wà lẹ́nu bodè Samaria; gbogbo àwọn wolii sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú wọn.
11. Ọ̀kan ninu wọn tí ń jẹ́ Sedekaya, ọmọ Kenaana fi irin ṣe ìwo, ó sì wí fún Ahabu pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ohun tí ìwọ óo fi bá àwọn ará Siria jà nìyí títí tí o óo fi ṣẹgun wọn patapata.”
12. Nǹkan kan náà ni gbogbo àwọn wolii yòókù ń wí, gbogbo wọn ní kí Ahabu lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, wọ́n ní OLUWA yóo fún un ní ìṣẹ́gun.