12. Ṣugbọn nítorí ti Dafidi baba rẹ, n kò ní ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí ní àkókò tìrẹ. Ọmọ rẹ ni n óo já ìjọba gbà mọ́ lọ́wọ́.
13. Ṣugbọn n kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, n óo ṣẹ́ ẹ̀yà kan kù sí ọmọ rẹ lọ́wọ́, nítorí ti Dafidi iranṣẹ mi ati ìlú Jerusalẹmu tí mo ti yàn.”
14. OLUWA bá mú kí Adadi dojú ọ̀tá kọ Solomoni; Adadi yìí jẹ́ ìran ọba ní ilẹ̀ àwọn ará Edomu.
15. Ṣáájú àkókò yìí, nígbà tí Dafidi gbógun ti àwọn ará Edomu, tí ó sì ṣẹgun wọn, Joabu balogun rẹ̀ lọ sin àwọn tí wọ́n kú sógun, ó sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin Edomu;
16. nítorí pé Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní ilẹ̀ Edomu fún oṣù mẹfa, títí tí ó fi pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Edomu run.