29. Ahasaya jọba ní ilẹ̀ Juda ní ọdún kọkanla tí Joramu ọmọ Ahabu ti jọba ní Israẹli.
30. Nígbà tí Jehu dé Jesireeli, Jesebẹli gbọ́; ó lé tìróò, ó di irun rẹ̀, ó sì ń yọjú wo ìta láti ojú fèrèsé ní òkè.
31. Bí Jehu ti gba ẹnu ọ̀nà wọlé, Jesebẹli kígbe pé, “Ṣé alaafia ni, Simiri? Ìwọ tí o pa oluwa rẹ!”
32. Jehu bá gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ní, “Ta ló wà lẹ́yìn mi ninu yín?” Àwọn ìwẹ̀fà meji tabi mẹta sì yọjú sí i láti ojú fèrèsé.
33. Jehu bá ké sí wọn, ó ni, “Ẹ Jù ú sílẹ̀.” Wọ́n bá ju Jesebẹli sí ìsàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sí ara ògiri ati sí ara àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jehu sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kọjá.
34. Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó mu, lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹ lọ sin òkú obinrin ẹni ègún yìí nítorí pé ọmọ ọba ni.”