Àwọn Ọba Keji 4:14-20 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?”Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.”

15. Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà.

16. Eliṣa sọ fún un pé, “Níwòyí àmọ́dún, o óo fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkunrin.”Obinrin náà dáhùn pé, “Háà! Oluwa mi, eniyan Ọlọrun ni ọ́, nítorí náà má ṣe parọ́ fún iranṣẹbinrin rẹ.”

17. Ṣugbọn obinrin náà lóyún ó sì bí ọmọkunrin ní akoko náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Eliṣa.

18. Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí ọmọ náà dàgbà, ó lọ bá baba rẹ̀ ninu oko níbi tí wọ́n ti ń kórè.

19. Lójijì, ó kígbe pe baba rẹ̀, ó ní, “Orí mi! Orí mi!”Baba rẹ̀ sì sọ fún iranṣẹ kan kí ó gbé ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.

20. Nígbà tí iranṣẹ náà gbé ọmọ náà dé ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ gbé e lé ẹsẹ̀ títí ọmọ náà fi kú ní ọ̀sán ọjọ́ náà.

Àwọn Ọba Keji 4