Àwọn Adájọ́ 5:11-13 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ẹ tẹ́tí sí ohùn àwọn akọrin lẹ́bàá odò,ibẹ̀ ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ́gun OLUWA,ọ̀rọ̀ ìṣẹ́gun àwọn eniyan rẹ̀ ní Israẹli.Àwọn eniyan OLUWA sì yan jáde láti ẹnubodè ìlú wọn.

12. Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀! Debora!Gbéra ńlẹ̀! Gbéra ńlẹ̀, kí o dárin!Dìde, Baraki, máa kó àwọn tí o kó lógun lọ,ìwọ ọmọ Abinoamu!

13. Àwọn akikanju yòókù bẹ̀rẹ̀ sí yan bọ̀,àwọn eniyan OLUWA náà sì ń wọ́ bọ̀,láti gbógun ti alágbára.

Àwọn Adájọ́ 5