Àwọn Adájọ́ 13:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, OLUWA sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Wọ́n sin àwọn ará Filistia fún ogoji ọdún.

2. Ọkunrin kan wà, ará Sora, láti inú ẹ̀yà Dani, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Manoa; àgàn ni iyawo rẹ̀, kò bímọ.

3. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, angẹli OLUWA fi ara han iyawo Manoa yìí, ó wí fún un pé, “Lóòótọ́, àgàn ni ọ́, ṣugbọn o óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan.

Àwọn Adájọ́ 13