11. Ẹ̀ ń rẹ́ talaka jẹ, ẹ sì ń fi ipá gba ọkà wọn. Nítòótọ́, ẹ ti fi òkúta tí wọ́n dárà sí kọ́ ilé, ṣugbọn ẹ kò ní gbé inú wọn; ẹ ti ṣe ọgbà àjàrà dáradára, ṣugbọn ẹ kò ní mu ninu ọtí waini ibẹ̀.
12. Gbogbo ìwà àìdára yín ni mo mọ̀, mo sì mọ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ti tóbi tó, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fìyà jẹ olódodo, tí ẹ̀ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ẹ sì ń du àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn lẹ́nu ibodè.
13. Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbọ́n yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní irú àkókò yìí, nítorí pé àkókò burúkú ni.