Aisaya 33:5-9 BIBELI MIMỌ (BM)

5. A gbé OLUWA ga!Nítorí pé ibi gíga ni ó ń gbé;yóo mú kí ìdájọ́ òtítọ́ ati òdodo kún Sioni.

6. Yóo mú kí ìdúróṣinṣin wà ní gbogbo àkókò rẹ̀.Yóo fún ọ ní ọpọlọpọ ìgbàlà, ati ọgbọ́n, ati ìmọ̀,ìbẹ̀rù OLUWA ni ìṣúra rẹ̀.

7. Ẹ wò ó, àwọn alágbára ń kígbe lóde,àwọn òjíṣẹ́ alaafia ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.

8. Òpópó ọ̀nà ṣófo,àwọn èrò kò rìn mọ́;wọ́n ń ba majẹmu jẹ́,wọn kò bìkítà fún ẹlẹ́rìí mọ́;wọ́n kò sì ka eniyan sí.

9. Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé.

Aisaya 33