Aisaya 27:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo fi idà rẹ̀ tí ó mú, tí ó tóbi, tí ó sì lágbára,pa Lefiatani, ejò tí ó ń fò,Lefiatani, ejò tí ń lọ́ wérékéké,yóo sì pa ejò ńlá tí ń bẹ ninu òkun.

2. Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé,

3. “Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀,lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín;tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọkí ẹnìkan má baà bà á jẹ́.

4. Inú kò bí mi,ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀,ǹ bá gbógun tì wọ́n,ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀.

5. Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò,kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa;kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.”

Aisaya 27