3. wọ́n gba orí alagbalúgbú omi kọjá lọ.Èrè yín ni ọkà ìlú Sihori,ìkórè etí odò Naili.Ẹ̀yin ni ẹ̀ ń ṣòwò káàkiri àgbáyé.
4. Ojú tì ọ́, ìwọ Sidoninítorí òkun ti fọhùn, agbami òkun ti sọ̀rọ̀, ó ní:“N kò rọbí, bẹ́ẹ̀ ni n kò bímọ;n kò tọ́ àwọn ọmọ dàgbà ríkì báà ṣe ọmọkunrin tabi ọmọbinrin.”
5. Nígbà tí ìròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Tire bá dé Ijiptiàwọn ará Ijipti yóo kérora.
6. Ẹ kọjá lọ sí Taṣiṣi.Ẹ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,ẹ̀yin tí ó ń gbé etí òkun.
7. Ṣé ìlú olókìkí yín náà nìyí,tí a ti tẹ̀dó láti ìgbà àtijọ́!Tí ó fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè,tí ó ṣe àlejò lọ sibẹ!