Títù 3:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí. Mo sì fẹ́ kí ó ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀, kí àwọn tí wọ́n ti gbàgbọ́ nínú Olúwa le kíyèsí láti máa fi ara wọn jìn fún iṣẹ́ rere. Nǹkan wọ̀nyìí dára, wọ́n sì jẹ èrè fún gbogbo ènìyàn.

9. Ṣùgbọ́n yẹra kúrò nínú àwọn ìbéèrè òmùgọ̀, àti ìtàn ìran, àti àríyànjiyàn àti ìjà nípa ti òfin, nítorí pé àwọn nǹkan báyìí jẹ́ aláìlérè àti asán.

10. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ dá ìyapa sílẹ̀ láàrin yín, ẹ bá a wí lẹ́ẹ̀kínní àti lẹ́ẹ̀kejì. Lẹ́yìn náà, ẹ má ṣe ní ohunkóhun íṣe pẹ̀lú rẹ̀.

11. Kí ó dá ọ lójú wí pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti yapa, ó jẹ́ ẹlẹ́sẹ̀, ó sì dá ara rẹ̀ lẹ́ni.

Títù 3