Sekaráyà 12:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Àti àwọn baálẹ̀ Júdà yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jérúsálẹ́mù ni agbára mi nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.’

6. “Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò se àwọn baálẹ̀ Júdà bí ààrò iná kan láàrin igi, àti bi ẹfúùfù iná láàrin ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jérúsálẹ́mù ní ipò rẹ̀.

7. “Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Júdà là ná, kí ògo ilé Dáfídì àti ògo àwọn ara Jérúsálẹ́mù má ba gbé ara wọn ga sí Júdà.

8. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dáfídì; ilé Dáfídì yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí ańgẹ́lì Olúwa níwájú wọn.

9. Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jérúsálẹ́mù.”

Sekaráyà 12