Sáàmù 92:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

9. Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá Rẹ, Olúwa,nítòótọ́ àwọn ọ̀ta Rẹ yóò ṣègbé;gbogbo àwọn olùṣe búburúní a ó fọ́nká.

10. Ìwọ tí gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó;òróró dídára ni a dà sími ní orí.

11. Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀ta mi;ìparun sí àwọn ènìyàn búburútí ó dìde sí mi.

12. Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,wọn yóò dàgbà bí i igi kédárì Lẹ́bánónì;

13. Tí a gbìn si ilé Olúwa,Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.

14. Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbówọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,

Sáàmù 92