Sáàmù 86:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nínú àwọn òrìṣà kò sì ẹni tí ó dà bí Rẹ, Olúwa:kò sí àwọn iṣẹ́ tí a le fi wé tìrẹ.

9. Gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ dáyóò wá, láti wá jọ́sìn níwájú Rẹ, Olúwa;wọn o mú ògo wà fún orúkọ Rẹ̀.

10. Nítorí pé ìwọ tóbi, ìwọ si ń ṣe ohun ìyanu;ìwọ nìkan ní Ọlọ́run.

11. Kọ́ mi ní ọ̀nà Rẹ, Olúwa,èmi ó sì máa rìn nínú òtítọ́ Rẹ;fún mi ní ọkàn tí kì í yapa,kí èmi kí ó ba lè bẹ̀rù orúkọ Rẹ.

Sáàmù 86