Sáàmù 83:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Áṣurí pẹ̀lú tí darapọ̀ mọ́ wọnláti ràn àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì lọ́wọ́. Sela

9. Ṣe sí wọn bí ìwọ ti ṣe sí Mídíánìbí o ti ṣe sí Sísérà àti Jábínì ní òdò Kíṣíónì,

10. Ẹni tí ó ṣègbé ní Éndórítí wọn sì dàbí ààtàn ní orí ilẹ̀.

11. Ṣe àwọn ọlọ́lá wọn bí Orébù àti Séébù,àwọn ọmọ aládé wọn bí Ṣébà àti Sálmúnà,

12. Tí ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a gbà ní ìníẸni pápá oko tútù Ọlọ́run.”

13. Ìwọ Ọlọ́run, Ṣe wọn bí ààjà,bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́.

14. Bí ìna ti i jó ìgbẹ́ ìgbóàti bí ọ̀wọ́ iná ti ń mú òkè-ńlá gbiná,

Sáàmù 83