1. Ọlọ́run àwọn orílẹ̀ èdè ti wà ilẹ̀ ìní Rẹ;wọn ti bá tẹ́ḿpìlì mímọ́ Rẹ jẹ́,wọn di Jérúsálẹ́mù kù sí òkìtì àlàpà.
2. Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,ẹran ara àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
3. Wọ́n tú ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omiyí Jérúsálẹ́mù ká,kò sì sí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
4. Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí o yí wa ká,àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wá ká.