Sáàmù 77:2-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,mo wá Olúwa;ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ọkàn mí sì kọ láti tùú nínú.

3. Èmi rántí i Rẹ, Ọlọ́run,mo sì kẹ́dùn;mo ṣe àroyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela

4. Ìwọ kò fẹ́ kí èmi fí ojú ba òorùn,mo dàámú tó bẹ́ẹ̀ tí ń kò le sọ̀rọ̀.

5. Mo ronú nípa ọjọ́ ìgbàanì;ọdún pípẹ́ sẹ́yìn;

6. Mo rántí orin mi ní òru.Èmi ń bá àyà mí sọ̀rọ̀,ọkàn mí sì ń ṣe àwárí jọjọ.

7. Olúwa yóò ha kọ̀ títí láé?Kí yóò ha ṣe ojú rere Rẹ̀ mọ́

8. Ṣe ìfẹ́ Rẹ̀ àti àánú Rẹ̀ tí kú lọ láéláé?Ìlérí Rẹ̀ ha kùnà títí ayé?

9. Ọlọ́run ha gbàgbé láti máa ṣàánú?Ní ìbínú Rẹ̀, ó ha sé ojú rere Rẹ̀ mọ́? Sela

Sáàmù 77