Sáàmù 77:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mó kígbe sí Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́;mo kígbe sí Ọlọ́run láti gbọ́ tèmi.

2. Nígbà tí mo wà nínú ìpọ́njú,mo wá Olúwa;ní òru ni mo na ọwọ́ mi jáde ní àìkáárẹ̀ọkàn mí sì kọ láti tùú nínú.

3. Èmi rántí i Rẹ, Ọlọ́run,mo sì kẹ́dùn;mo ṣe àroyé, ẹ̀mí mi sì rẹ̀wẹ̀sì. Sela

Sáàmù 77