Sáàmù 69:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Jẹ́ kí tábìlì wọn kí ó dí ìkẹ́kùnni iwájú wọn, kí ó sì di okùn dídẹfún àwọn tó wà ní àlàáfíà.

23. Kí ojú wọn kií ó ṣókùnkùn kí wọ́n má ṣe ríran,kí eyín wọn di títẹ̀ títí láé.

24. Tú ìbínú Rẹ jáde sí wọn;kí ìbínú gbígbóná Rẹ bò wọ́n mọ́lẹ̀.

25. Kí ibùjókòó wọn di ahoro;kí ẹnikẹ́ni má ṣe gbé nínú wọn.

26. Nítorí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí ẹni tí ìwọ ti lù,àti ìrora àwọn tí ó ti ṣèṣe

Sáàmù 69