12. “Àwọn ọba àti àwọn ológun yára sálọ;Obìnrín tí ó sì jókòó ni ilé ní ń pín ìkógun náà.
13. Nígbà tí ẹ̀yin sùn láàrin àwọn àgọ́ iná,nígbà náà ni ẹ̀yin ó dàbí apá àdàbà ti a bò ní sílífa.”
14. Nígbà ti Olódùmarè fọ́n àwọn ọba ká ní ilẹ̀ náà,ó dàbí òjò dídi ní Salímónì.
15. Òkè Básánì jẹ́ òkè Ọlọ́run;òkè tí ó ní orí púpọ̀ ní òkè Básánì.
16. Kí ló dé ti ẹ̀yin fi ń lára,ẹ̀yin òkè wúwo, òkè tí Ọlọ́run ti fẹ́ láti jọbaníbi tí Ọlọ́run fúnrarẹ̀ yóò máa gbé títí láé?