12. Ìwọ mú àwọn ènìyàn gun wá ní oríàwa la iná àti omi kọjáṣùgbọ́n ìwọ mú wa dé ibi ọ̀pọ̀.
13. Èmi ó wá sí tẹ́ḿpìlì Rẹ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísunkí n sì mú ẹ̀jẹ́ mi ṣẹ sí ọ
14. Ẹ̀jẹ́ ti ètè mi jẹ́, tí ẹnu mi sì sọnígbà tí mo wà nínú ìsòro.
15. Èmi o sun ẹbọ ọlọ́ràá sí ọàti ẹbọ ọ̀rá àgbò;èmi o rú akọ màlúù àti ewúrẹ́. Sela
16. Ẹ wá gbọ́ gbogbo ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù Olúwa;ẹ jẹ́ kí n sọ ohun tí ó ṣe fún mi.