Sáàmù 60:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ Rẹ̀:“Ní ayọ̀, èmi ó pín ṣèkémù jádeèmi o sì wọ̀n àfonífojì ṣúkótù.

7. Tèmi ni Gílíádì, tèmi sì ni Mánásè;Éfúráímù ni àsìbórì mi,Júdà sì ní ọ̀pá àṣẹ mi.

8. Móábù ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,lórí Édómù ní mo bọ́ bàtà mi sí;lórí fìlísitinì ni mo kígbe ayọ̀.”

9. Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Édómù?

10. Kí ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?

11. Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,nítorí asán ní ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.

12. Nípa Ọlọ́run ni a ó ní ìṣẹ́gun,yóò sì tẹ̀ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Sáàmù 60