Sáàmù 59:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Kíyèsí ohun tí wọ́n tú jáde ní ẹnu:wọn ń tú idà jáde láti ètè wọn,wọn sì wí pé, “Ta ní ó le gbọ́ ọ̀rọ̀ wa?”

8. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, yóò fi wọ́n rẹ́rin-ínÌwọ ó yọ ṣùtì sí gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè.

9. Ìwọ agbára mi, èmi ó máa kọrin ìyìn sí ọ;nítorí ìwọ Ọlọ́run ni ààbò mi,

10. Ọlọ́run àánú mi ni yóò ṣáájú mi.Ọlọ́run yóò sì jẹ́ kí èmi rí ìfẹ́ mi lára àwọn ọ̀tá mi.Yóò sì jẹ́ kí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gún lórí àwọn ọ̀tá ìfẹ́ àwọn ọ̀ta mi.

11. Ṣùgbọ́n má ṣe pa wọ́n, Olúwa asà wa,kí àwọn ènìyàn mí má ba à gbàgbé.Nínú agbára Rẹ̀, jẹ́ kí wọ́n máa rìn kiri,kí ó sì Rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

12. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ẹnu wọn,ni ọ̀rọ̀ ètè wọn,kí a mú wọn nínú ìgbéraga wọn.Nítorí ẹ̀gàn àti èké tí wọn ń sọ,

13. Pa wọn run nínú ìbínú,run wọ́n di ìgbà tí wọ́n kò ní sí mọ́.Nígbà náà ní yóò di mímọ̀ dé òpin ayépé Ọlọ́run jọba lórí Jákọ́bù. Sela

Sáàmù 59