Sáàmù 58:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atinilójú,bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.

6. Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;ní ẹnu wọnká ọ̀gan àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.

7. Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń ṣàn lọ;nígbà tí ó bá fa ọfà Rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.

8. Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí Rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbébí ọmọ ti oṣu Rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí òòrùn.

9. Kí ìkòkò yín kì o tó mọ̀ ìgbóná ẹ̀gún;ìbá tutù, ìbá ma jò, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.

Sáàmù 58