Sáàmù 50:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Bí ebi tílẹ̀ ń pá mí, èmi kì yóò sọ fún ọ,nítorí ayé ni tèmi àti ohun gbogbotí ó wa ní inú Rẹ̀.

13. Ǹjẹ èmi yóò ha jẹ ẹran akọ màlúù tàbímú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́?

14. Rú ẹbọ ọrẹ sí Ọlọ́runsan ẹ̀jẹ̀ Rẹ fún ọ̀gá ògo,

15. Kí o sì pe mí ni ọjọ́ ìpọ́njú,èmi yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì bu ọlá fún mi.

16. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ fún àwọnènìyàn búburú:“Kí ní ẹ̀tọ́ tí o ní tí ìwọ fi ń tún àwọn ìlànà mi sọtàbí tí ìwọ sì ń sọ májẹ̀mu mi ní ẹnu Rẹ?

17. Ìwọ kórìíra àsẹ miìwọ sì sá ọ̀rọ̀ mí tì sí apá kan

18. Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́-ọnìwọ sì da ara Rẹ̀ dé àwọn alágbèrè

19. Ìwọ lo ẹnu Rẹ̀ fún aburúìwọ sì ń fi ahọ́n Rẹ pète ẹ̀tàn

Sáàmù 50