Sáàmù 48:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó dára nínú ipò ìtẹ́ Rẹ̀ayọ̀ gbogbo ayéòkè Síónì, ní ìhà àríwání ìlú ọba ńlá.

3. Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin Rẹ̀;ó fi ara Rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

4. Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ

5. Wọn ríi bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́na yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ

6. Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí

Sáàmù 48