9. Àwọn ọmọbìnrin àwọn aládé wànínú àwọn àyànfẹ́ Rẹ̀ní ọwọ́ ọ̀tún Rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúrónínú wúrà ófórì.
10. Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí Rẹ̀ símigbàgbé àwọn ènìyàn Rẹ àti ilé baba Rẹ
11. Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà Rẹ gidigidinítorí òun ni Olúwa Rẹkí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12. Ọmọbìnrin ọba tirẹ̀ yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùnàwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojú rere Rẹ̀.