Sáàmù 44:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

14. Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀ èdè;àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.

15. Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,

16. nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tànní ojú àwọn ọ̀ta àti olùgbẹ̀san.

17. Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,ṣíbẹ̀ àwa kò gbàgbé Rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mu Rẹ̀.

18. Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà Rẹ̀.

Sáàmù 44