Sáàmù 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Dá mi lóhùn nígbà tí mo bá pè ọ́,iwọ Ọlọ́run òdodo mi,Fún mi ní ìdánídè nínú ìpọ́njú mi;ṣàánú fún mi, kí o sì gbọ́ àdúrà mi.

2. Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó, ẹyin ọmọ ènìyàn, tí ẹ ó ṣe sọ ògo mi di ìtìjú?Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó,tí ẹ̀yin yóò ṣe fẹ́ràn ìtànjẹ́ àti tí ẹ̀yin yóò fi máa wá Ọlọ́run èké?

3. Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo ṣọ́tọ̀ fún ara Rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.

Sáàmù 4