Sáàmù 37:27-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Lọ kúrò nínú ibi,kí o sì máa ṣe rere;nígbà náà ni ìwọ gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.

28. Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ Rẹ̀ sílẹ̀.Àwọn olódodo ni a ó pamọ́títí ayérayé,ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburúní a ó ké kúrò.

29. Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.

30. Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,ahọ́n Rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.

31. Òfin Ọlọ́run Rẹ̀ ń bẹní àyà wọn;àwọn ìgbẹ́sẹ̀ Rẹ̀ kì yóò yẹ̀.

Sáàmù 37