Sáàmù 35:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà náà ni ọkàn miyóò yọ̀ nínú Olúwa,àní ayọ̀ ńlá nínú ìgbàlà Rẹ̀.

10. Gbogbo egúngún mi yóò wí pé,“ìwọ Olúwa,ta ni ó dà bí i Rẹ̀?O gba talákà làlọ́wọ́ àwọn tí ó lágbárajù wọ́n lọ,talákà àti aláìnílọ́wọ́ ẹni tí ń fi ṣe ìkógun?”

11. Àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde;wọ́n bi mi léèrè àwọn ohuntí èmi kò mọ̀.

12. Wọ́n fi búburú san ire fún mi;láti sọ ọkàn mi di òfo.

13. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi ni,nígbà tí wọn ń ṣe àìsàn,mo wọ aṣọ ọ̀fọ̀;mo fi ààwẹ̀ pọ́n ara mi lójú.Mo gba àdúrà pẹ̀lú ìtẹríbaní oókan àyà mi;

14. bí i ẹni wí pé ọ̀rẹ́ tàbí ẹ̀gbọ́nmi ní wọ́n;mo ń lọọ́ kiri bí ẹni tíń sọ̀fọ̀ fún ìyà Rẹ̀,tí o tẹríba nínú ìbànújẹ́.

15. Ṣùgbọ́n nínú ìkọ̀sẹ̀ miwọ́n kó ara wọn jọ wọ́n sì yọ̀,wọ́n kó ara wọn jọ sí mi;àní àwọn tí èmi kò mọ̀wọ́n fà mí yawọ́n kò sì dákẹ́.

16. Àwọn àgàbàgebè ń ṣe yẹ̀yẹ́mi ṣíwájú àti sí wájú síiwọ́n pa eyín wọnkeke sí mi.

Sáàmù 35