23. Jí dìde!Ru ara Rẹ̀ sókè fún ààbò mi,fún ìdí mi,Ọlọ́run mi àti Olúwa mi!
24. Dá mi láre,ìwọ Olúwa,Ọlọ́run mi,gẹ́gẹ́ bí òdodo Rẹ,kí o má sì ṣe jẹ́ kíwọn kí ó yọ̀ lórí mi!
25. Má ṣe jẹ́ kí wọn wínínú ara wọn pé,“Áà! Àti rí ohun tí ọkànwa ń fẹ́:Má ṣe jẹ kí wọn kí ó wí pé,a ti gbé e mì.”
26. Kí ojú kí ó tì wọ́n,lí wọn kí ó sì dààmú pọ̀,tí ń yọ̀ sí ìyọnu mikí a fi ìtìjú àti àbùkù wọ̀ wọ́n ní aṣọtí ń gbéraga sí mi.