Sáàmù 35:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí;kí o sì kọ ojú ìjà sí àwọn tí ó ń bá mi í jà!

2. Di aṣà àti àpáta mú,kí o sì dìde fún ìrànlọ́wọ́ mi!

3. Fa idà àti ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojúkọ àwọn tí ń lé mi;sọ fún ọkàn mi pé, “Èmi ni ìgbàlà Rẹ.”

Sáàmù 35