Sáàmù 33:10-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Olúwa ti mú ìmọ̀ràn àwọn orílẹ̀ èdè wá sí asán;ó sì mú àrékérekè àwọn ènìyàn di ṣíṣákìí.

11. Ìgbìmọ̀ Olúwa dúró títí ayérayé,àní ìrò inú Rẹ̀ láti ìrandíran ni.

12. Ìbùkún ni fún orílẹ̀ èdè náà Ọlọ́run ẹni tí Olúwa jẹ́ tirẹ̀,àti àwọn ènìyàn náà tí ó ti yàn ṣe ìní Rẹ̀.

13. Olúwa wò láti ọ̀run wá;Ó sì rí gbogbo ìran ènìyàn.

14. Níbi tí ó ti jókòó lóríi ìtẹ́Ó wo gbogbo àwọn olùgbé ayé

15. ẹni tí ó ṣe àyà wọn bákan náà,ó sì kíyèsí ìṣe wọn.

16. A kò gba ọba kan là nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun;kò sì sí jagunjagun tí a gbà sílẹ̀ nípa agbára ńlá Rẹ̀.

Sáàmù 33