Sáàmù 31:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ṣàánú fún mi, ìwọ Olúwa, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú;ojú mi fi ìbìnújẹ́ sùn,ọkàn àti ara mi pẹ̀lú.

10. Èmi fi ìbànújẹ́ lo ọjọ́ miàti àwọn ọdún mi pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn;agbára mi ti kùnà nítorí òṣì mi,egungun mi sì ti rún dànù.

11. Èmi di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn ọ̀tá mi gbogbo,pẹ̀lú pẹ̀lú láàrin àwọn aládùúgbò mi,mo sì di ẹ̀rù fún àwọn ojúlùmọ̀ mi;àwọn tí ó rí mi ní òde ń yẹra fún mi.

Sáàmù 31