Sáàmù 31:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Ṣùgbọ́n èmí gbẹ́kẹ̀lé ọ, ìwọ OlúwaMo sọ wí pé, “Ìwọ ní Ọlọ́run mi.”

15. Ìgbà mi ń bẹ ní ọwọ́ Rẹ;gbà mí kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá miàti àwọn onínúnibíni.

16. Jẹ́ kí ojú ù Rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ìrànṣẹ́ Rẹ lára;Gbà mí nínú ìfẹ́ẹ̀ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

17. Má ṣe jẹ́ kí á fi mí sínú ìtijú, Olúwa;nítorí pé mo ké pè ọ́;jẹ́ kí ojú kí ó ti ènìyàn búburú;jẹ́ kí wọ́n lọ pẹ̀lú ìdààmú sí isà òkú.

18. Jẹ́ kí àwọn ètè irọ́ kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́pẹ̀lú ìgbéraga àti ìkẹ́gàn.wọ́n sọ̀rọ̀ àfojúdi sí olódodo.

19. Báwo ni títóbi oore Rẹ̀ ti pọ̀ tó,èyí tí ìwọ ti ní ní ìpamọ́ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ,èyí tí ìwọ rọ̀jò Rẹ̀ níwájú àwọn ènìyàntí wọ́n fi ọ́ se ibi ìsádi wọn.

Sáàmù 31