Sáàmù 30:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Nípa ojúrere Rẹ̀, Olúwa,ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;ìwọ pa ojú Rẹ mọ́,àyà sì fò mí.

8. Sí ọ Olúwa, ni mo képè;àti sí Olúwa ni mo sunkún fún àánú:

9. “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,nínú lílọ sí ihò mi?Eruku yóò a yìn ọ́ bí?Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo Rẹ?

10. Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”

Sáàmù 30