1. Olúwa, báwo ni àwọn ọ̀ta mi ṣe pọ̀ tó!Báwo ni àwọn ti ó dìde sí mi ṣe pọ̀ tó!
2. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ń sọ ní ti tèmi, pé“Ọlọ́run kò ní gbà á là.”
3. Ṣùgbọ́n ìwọ ni àṣà yí mi ká, Olúwa;iwọ fi ogo fún mi, ìwọ sì gbé orí mi sókè.
4. Olúwa ni mo kígbe sókè sí,ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ Rẹ̀ wá.